2. Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí miláti jẹ ẹran ara mi,àní àwọn ọ̀ta mi àti àwọn abínúkú ù mi,wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
3. Bí ọmọ ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
4. Ohun kan ni mo bèèrè nípasẹ̀ Olúwa,òun ni èmi yóò máa wá kiri:kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwaní ọjọ́ ayé mi gbogbo,kí èmi: kí ó le kíyèsí ẹwà Olúwa,kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹ́ḿpìlì Rẹ.