1. Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OlúwaǸjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2. Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,dán àyà àti ọkàn mi wò;
3. Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ Rẹ.
4. Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìsòótọ́,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5. Èmi ti kórìírá àwùjọ àwọn ènìyàn búburúèmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6. Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ Rẹ ká Olúwa
7. Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.