Sáàmù 25:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. ṣe amọ̀nà mi nínú ọ̀títọ́ ọ Rẹ, kí ò si kọ́ mi,Nítoríi ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.

6. Rántí, áà! Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ̀ ńlá,torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́

7. Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mitàbí ìrékọjáà mi;gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ rántíì minítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.

8. Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:nítorí náà ó kọ́ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ni ọ̀nà náà.

9. Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà Rẹ̀.

Sáàmù 25