Sáàmù 22:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ṣíbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;ìwọ ni ó mú mi wà láìléwunígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.

10. Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wánígbà tí ìyá a mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi

11. Má ṣe jìnnà sími,nítorí pé ìyọnu sún mọ́ tòsíkò sì sí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12. Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;àwọn màlúù alágbára Báṣánì rọ̀gbà yí mi ká.

13. wọ́n ya ẹnu wọn, si mi bí i kìn-nìún tí ń dọdẹ kirití ń ké ramúramù.

Sáàmù 22