Sáàmù 20:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nisinsìnyí, èmi mọ̀ wí pé Olúwa pa ẹni-àmí-òróró Rẹ̀ mọ́;yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ Rẹ̀ wápẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀.

7. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.

8. Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọn sì ṣubú,ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.

9. Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

Sáàmù 20