Sáàmù 18:30-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà Rẹ̀ pé,a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwaòun ni àpáta ààbòfún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.

31. Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?Ta ní àpátà bí kò ṣe Olúwa wa?

32. Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrèó sì mú ọ̀nà mi pé.

33. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín;ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.

34. Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíja;apá mi lè tẹ ọrùn idẹ

35. Ìwọ fi àṣà ìṣẹ́gun Rẹ̀ fún mi,ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbé mí sókè;àti ìwà ìpẹ̀lẹ́ Rẹ̀ sọ mi di alágbára àti ẹni ńlá.

36. Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ mi di ńlá ní ìṣàlẹ̀ mi,kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.

Sáàmù 18