23. Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Rẹ̀;mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24. Olúwa san ẹ̀ṣan fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú Rẹ̀.
25. Sí olóòótọ́ ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní olóòtọ́,sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26. Sí ọlọ́kan mímọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27. O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n o Rẹ̀ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28. Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mikí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.