Sáàmù 17:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;fi etí sí igbe mi.Tẹ́ti sí àdúrà mití kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.

2. Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;kí ojú Rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

3. Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì yẹ̀ mí wò ní òru.Bí ìwọ bá dán mi wò, ìwọ kì yóò rí ohunkóhunèmi ti pinnu pé ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.

4. Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyànnípa ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹèmi ti pa ara mi mọ́kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.

Sáàmù 17