Sáàmù 148:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wáẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbiàti ẹ̀yin ibú òkun

8. Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyínìdí omi àti àwọn ìkùùku,ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;

9. Òkè ńlá àti gbogbo òkè kékèké,igi eléso àti gbogbo igi kédárì,

10. Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìngbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:

11. Àwọn ọba ayé àti ènìyàn áye gbogboàwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn onídájọ́ ayé,

12. Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrinàwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

Sáàmù 148