4. Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi;ọkàn mi tí ó wà nínú mi dààmú.
5. Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ Rẹmo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ Rẹ ti ṣe.
6. Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:òrùgbẹ Rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela
7. Dámilóhùn kánkán, Olúwa; ó Rẹ̀ ẹ̀mí miMá ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lára mitàbí èmi yóò dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
8. Jẹ́ kí òwúrọ̀ mú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí kì í kùnà wá fún mi,nítorí èmi ti gbẹ́kẹ̀ mi lé ọ.Fí ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,nítorí sí ọ ni èmi gbé ọkàn mi sókè.