1. Èmi kígbe sókè sí Olúwa;Èmi gbé ohùn mi sókèsí Olúwa fún àánú.
2. Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú Rẹ̀bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú Rẹ̀.
3. Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣààrẹ̀ nínú mi,ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìnènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
4. Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì wò ókò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún mièmi kò ní ààbò;kòsí ẹni tí ó ṣe àníyàn fún ayé mi.