Sáàmù 140:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi kákiri ni,jẹ́ kí ìka ètè ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.

10. A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,sínú ọ̀gbun omi jínjìn,kí wọn kí ó má bà le dìde mọ́.

11. Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹṣẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.

12. Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,yóò si ṣe ètò fun àwọn tálákà

13. Nítòótọ́ àwọn olódodo yóòmáa fi ọpẹ́ fún orúkọ Rẹ;àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú Rẹ.

Sáàmù 140