Sáàmù 137:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílóò,tí ó wà láàrin Rẹ̀.

3. Nítorí pé níbẹ̀ ní àwọntí ó kó wa ní ìgbékùn bèèrè orin lọ́wọ́ wá,àti àwọn tí ó ni wá lára bèèrè ìdárayá wí pé;ẹ kọ orin Síónì kan fún wa.

4. Àwa o ti ṣe kọ orin Olúwa ni ilẹ̀ àjèjì

5. Jérúsálẹ́mù, bí èmi bá gbàgbé Rẹjẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò Rẹ.

6. Bí èmi kò bá rántí Rẹ,jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;bí èmi kò bá fi Jérúsálẹ́mù ṣáájúolórí ayọ̀ mi gbogbo.

7. Olúwa rántí ọjọ́ Jérúsálẹ́mù,lára àwọn ọmọ Édómù,àwọn ẹni tí ń wí pé,wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ de ìpílẹ̀ Rẹ̀!

8. Ìwọ, ọmọbìnrin Bábílónì, ẹni tí a o parun;ìbùkún ní fún ẹni tí ó san án fúnọ bí ìwọ ti rò sí wa.

Sáàmù 137