Sáàmù 135:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Éjíbítì,àti tí ènìyàn àti ti ẹranko.

9. Ẹni tí ó rán àmì àti iṣẹ ìyanu sí àrin Rẹ̀,ìwọ Éjíbítì, sí ara Fáráò,àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ gbogbo.

10. Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀,tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.

11. Síónì, ọba àwọn ará Ámorì, àti Ógù,ọba Báṣánì, àti gbogbo ìjọba Kénánì:

12. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní,ìní fún Ísírẹ́lì, ènìyàn Rẹ̀.

Sáàmù 135