Sáàmù 132:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,

5. Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,ibùjókòó fún Alágbára Jákọ́bù.

6. Kíyèsí i, àwa gbúroo Rẹ̀ ni Éfúrátà:àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.

7. Àwa ó lọ sínú àgọ́ Rẹ̀:àwa ó máa sìn níbi àpótí-ìtìsẹ̀ Rẹ̀

8. Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi Rẹ:ìwọ, àti àpótí agbára Rẹ.

9. Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà Rẹ:kí àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

Sáàmù 132