Sáàmù 130:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nítorí ìdàríjìn wà lọ́dọ̀ Rẹ,kí a lè máa bẹ̀rù Rẹ.

5. Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,àti nínú ọ̀rọ̀ Rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí

6. Ọkàn mi dúró de Olúwa,ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,àní ju àwọn ti ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

7. Ísírẹ́lì, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,àti lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáńdè wà.

8. Òun ó sì dá Ísírẹ́lì ní ìdèkúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ gbogbo.

Sáàmù 130