Sáàmù 128:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Obìnrin Rẹ yóò dà bí àjàrà rereeléso púpọ̀ ní àárin ilé Rẹ;àwọn ọmọ Rẹ yóò dà bí igi olífì tí ó yí tábìlì Rẹ ká.

4. Kíyèsíi pé, bẹ́ẹ̀ ni a o bù síi fún ọkùnrin náà,tí o bẹ̀rù Olúwa.

5. Kí Olúwa kí o bù síi fún ọ láti Síónì wá,kí ìwọ kí ó sì máa rí ireJérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ayé Rẹ gbogbo.

6. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí o sì máa rí àti ọmọ dé ọmọ Rẹ;àti àlàáfíà lára Ísírẹ́lì.

Sáàmù 128