46. Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin Rẹ níwájú àwọn ọbaojú kì yóò sì tì mí,
47. Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ Rẹnítórí èmi ni ìfẹ́ wọn.
48. Èmi gbé ọwọ̀ mi sókè nítorí àṣẹ Rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,èmi sì ń ṣe àsàrò òfin Rẹ̀.
49. Rántí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50. Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:ìpinu Rẹ pa ayé mi mọ́.
51. Àwọn agbéraga fi mi ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin Rẹ.
52. Èmi rántí àwọn òfin Rẹ ìgbàanì, Olúwa,èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53. Ìbínú dìmí mú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburútí wọ́n ti kọ òfin Rẹ sílẹ̀.