Sáàmù 119:27-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Jẹ́ kí ń mọ ẹ̀kọ́ ìlànà Rẹ̀:nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu Rẹ.

28. Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

29. Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tànfún mi ní oore ọ̀fẹ́ nípa òfin Rẹ.

30. Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin Rẹ.

31. Èmi yára di òfin Rẹ mú. Olúwamá ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

32. Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ,nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

Sáàmù 119