Sáàmù 119:23-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọ̀pọ̀, wọ́nń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ Rẹ.

24. Òfin Rẹ ni dídùn inú mi;àwọn ní olùbadámọ̀ràn mi.

25. Èmi tẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ sínú erùpẹ̀;pa ayé mi mọ́ sí ipa ọ̀rọ̀ Rẹ.

26. Èmi tún ọ̀nà mi síròṣ ìwọ sì dá mí lóhùn;kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

27. Jẹ́ kí ń mọ ẹ̀kọ́ ìlànà Rẹ̀:nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu Rẹ.

28. Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

Sáàmù 119