Sáàmù 119:155-160 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

155. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburúnítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ.

156. Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, Olúwa;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

157. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀ta tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,ṣùgbọ́n èmi kò tíì yí padà kúrò nínú òfin Rẹ.

158. Èmi wọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́.

159. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Rẹ;pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ.

160. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ;gbogbo òfin òdodo Rẹ láéláé ni.

Sáàmù 119