Sáàmù 119:154-164 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

154. Gba ẹjọ́ mi rò kí ó sì rà mí padà;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

155. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburúnítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ.

156. Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, Olúwa;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

157. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀ta tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,ṣùgbọ́n èmi kò tíì yí padà kúrò nínú òfin Rẹ.

158. Èmi wọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́.

159. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Rẹ;pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ.

160. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ;gbogbo òfin òdodo Rẹ láéláé ni.

161. Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

162. Èmi yọ̀ nínú ìpinnu Rẹbí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.

163. Èmi kórìíra mo sì gba èké ṣíṣeṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin Rẹ.

164. Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́nítorí òfin òdodo Rẹ.

Sáàmù 119