Sáàmù 119:133-139 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

133. Fi ìsísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ,má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.

134. Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ.

135. Jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ Rẹ lárakí ó sì kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.

136. Omijé sàn jáde ní ojú mi,nítorí wọn kò gba òfin Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.

137. Olódodo ni ìwọ Olúwaìdájọ́ rẹ sì dúró sinsin

138. Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.

139. Ìtara mi ti pami run,nítorí àwọn ọ̀ta mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ Rẹ dá.

Sáàmù 119