Sáàmù 119:129-145 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

129. Òfin Rẹ̀ ìyanu ni:nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.

130. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;ó fi òye fún àwọn òpè.

131. Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,nítorí èmi fojú sọ́nà sí ṣsẹ Rẹ.

132. Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọntí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ.

133. Fi ìsísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ,má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.

134. Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ.

135. Jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ Rẹ lárakí ó sì kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.

136. Omijé sàn jáde ní ojú mi,nítorí wọn kò gba òfin Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.

137. Olódodo ni ìwọ Olúwaìdájọ́ rẹ sì dúró sinsin

138. Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.

139. Ìtara mi ti pami run,nítorí àwọn ọ̀ta mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ Rẹ dá.

140. Wọ́n ti dán ìpinnu Rẹ wò pátapátaìránṣẹ́ Rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.

141. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gànèmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ.

142. Òdodo Rẹ wà títí láéòtítọ́ ni òfin Rẹ̀.

143. Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,ṣùgbọ́n àsẹ Rẹ ni inú dídùn mi,

144. Òfin Rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;fún mi ní òyé kí èmi lè yè.

145. èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:dámi lóhùn Olúwa,èmi yóò sì gbọ́ràn sí àsẹ Rẹ.

Sáàmù 119