11. Èmi ti pa ọ̀rọ̀ Rẹ mọ́ ní ọkàn mikí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
12. Ìyìn ni fún Olúwa;kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.
13. Pẹ̀lú ètè mi èmi tún sírògbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu Rẹ.
14. Èmi yọ̀ nínú títẹ̀lé òrin Rẹbí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọlá ńlá.
15. Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà Rẹèmi sì kíyèsí ọ̀nà Rẹ
16. Inú mi dùn sí àṣẹ Rẹ;èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà Rẹ.
17. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ, èmi yóò sì wà láàyè;èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ.
18. La ojú mi kí èmi lè ríran ríohun ìyanu tí ó wà nínú òfin Rẹ.
19. Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;Má ṣe pa àṣẹ Rẹ mọ́ fún mi.
20. Ọkàn mi pòrúúru pẹ̀lú ìfojúsọ́nànítorí òfin Rẹ nígbà gbogbo.
21. Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn-úntí ó sìnà kúrò nínú àṣẹ Rẹ.
22. Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,nítorí èmi pa òfin Rẹ mọ́.
23. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọ̀pọ̀, wọ́nń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ Rẹ.
24. Òfin Rẹ ni dídùn inú mi;àwọn ní olùbadámọ̀ràn mi.