107. A pọ́n mi lójú gidigidi; Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Rẹ
108. Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,kí o sì kọ́ mi ní òfin Rẹ̀.
109. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ minígbà gbogbo,èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.
110. Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,ṣùgbọ́n èmi kò sìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ.
111. Òfin Rẹ ni ogún mi láéláé;àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112. Ọkàn mi ti lé pípa òfin Rẹ mọ́láé dé òpin.
113. Èmi kóríra àwọn ọlọ́kàn méjì,ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin Rẹ.
114. Ìwọ ni ààbò mi àti aṣà mi;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.