20. Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwaibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21. Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dámi lóhùn;ìwọ sì di ìgbàlà mi.
22. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ni ó di pàtàkì òkúta igun ilé;
23. Olúwa ti ṣe èyíó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24. Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú Rẹ̀.
25. Olúwa, gbà wá; Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
26. Ìbùkún ni fún àwọn tí ó wá ní orúkọ Olúwa.Láti ilé Olúwa wá ní àwa fi ìbùkún fún ọ.