13. Ìwọ tì mi gidigidi kí ń lè subú,ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
14. Olúwa ni agbára àti orin mi;ó si di ìgbàlà mi.
15. Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:“ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
16. Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbé ga;ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
17. Èmi kì yóò kú ṣùgbọ́n èmi yóò yè,èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
18. Olúwa bá mi wí gidigidi,ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.