Sáàmù 116:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,“èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.

11. Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé“Èké ni gbogbo ènìyàn”.

12. Kí ni èmi yóò san fún Olúwanítorí gbogbo rere Rẹ̀ sí mí?

13. Èmi yóò gbé aago ìgbàlà sókèèmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.

14. Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwaní ojú àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15. Iyebíye ní ojú Olúwaàti ikú àwọn ẹni mímọ́ Rẹ̀.

16. Olúwa, ní tòótọ́ ìránṣẹ́ Rẹ ni mo jẹ́;èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ, ọmọ ìránṣẹ́-bìnrin Rẹ;ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

17. Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọèmi yóò sì képe orúkọ Olúwa

Sáàmù 116