Sáàmù 115:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kí ṣe fún wa, Olúwa kì ṣe fún wá,ṣùgbọ́n fún orúkọ Rẹ̀ ní a fi ògo fún,fún àánú àti òtítọ́ Rẹ.

2. Torí kí ní àwọn aláìkọlà yóò ṣe sọ pé,níbo ni Ọlọ́run wa wà.

3. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.

4. Òrìṣà fàdákà àti wúrà,iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn

5. Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

Sáàmù 115