Sáàmù 109:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Kí a dá a lẹbi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́kí àdúrà Rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀

8. Kí ọjọ́ Rẹ̀ kí ó kúrúkí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ Rẹ̀

9. Kí àwọn ọmọ Rẹ̀ di aláìní babakí aya Rẹ̀ sì di opó

10. Jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ máa ṣagbe kirikí wọn máa tọrọ ounjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn

11. Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó níjẹ́ kí àléjò kí o kó èrè isẹ́ Rẹ̀ lọ

12. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikan ṣe àánú fún untàbí kí wọn káàánú lóríàwọn ọmọ Rẹ̀ aláìní baba

Sáàmù 109