Sáàmù 107:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ó sì fi ìkorò Rẹ àyà wọn sílẹ̀;wọn ṣubú, kò sì sí ẹni tíyóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

13. Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn

14. Ó mú wọn jáde kúrò nínúòkùnkùn àti òjìji ikú,ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.

15. Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.

16. Nítorí tí ó já ilẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nìó sì ke irin wọ̀n nì ní agbede-méjì.

Sáàmù 107