41. Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀ èdè lọ́wọ́,àwọn ọ̀tá wọn sì jọba lórí wọn.
42. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọ́n lójúwọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,Ṣíbẹ̀ wọ́n si ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìwọ́n sì sòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44. Ṣùgbọ́n o kíyèsí wọn nítorí ìṣòronígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45. Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ nítorí wọnNítorí agbára ìfẹ́ Rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46. Lójú gbogbo àwọn tí o kó wọn ní ìgbèkùnó mú wọn rí àánú.