Sáàmù 106:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Wọn dá ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Péórù,wọn sì ń jẹ ẹbọ ti a rú sí àwọn òkú òrìṣà

29. Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣeàjàkálẹ̀-àrùn jáde láàrin wọn.

30. Ṣùgbọ́n Fínéhásì dìde láti dá sí i,àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán

31. A sì ka èyí sí òdodo fún un àtifún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀

32. Níbi omi Méríbà, wọn bí Ọlọ́run nínú,ohun búburú wá sí orí Mósè nítorí wọn.

Sáàmù 106