Sáàmù 105:21-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ Rẹ̀aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,

22. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ̀, kí ó máaṣe àkóso àwọn ọmọ aládékí ó sì kọ́ àwọn àgbà Rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23. Ísírẹ́lì wá sí Éjíbítì;Jákọ́bù sì ṣe àtìpó ní ilé Ámù.

24. Olúwa, sì mú àwọn ọmọ Rẹ̀ bí síió sì mú wọn lágbára jùàwọn ọ̀tá wọn lọ

25. Ó yí wọn lọkàn padà láti korìíra àwọn ènìyànláti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀.

26. Ó rán Mósè ìránṣẹ́ Rẹ̀àti Árónì tí ó ti yàn

27. Wọn ń ṣé iṣẹ́ ìyanu láàrin wọnó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Ámù

Sáàmù 105