Sáàmù 105:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ó fi da Jákọ́bù lójú gẹ́gẹ́ bí àṣẹsí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé

11. “Fún ìwọ ní èmi ó fún ní ilẹ̀ Kénánìgẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún”.

12. Nígbà tí wọn kéré níye,wọn kéré jọjọ, àti àwọn àjòjì níbẹ̀

13. Wọn ń lọ láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀ èdè,láti ìjọba kan sí òmìrán.

14. Kò gba ẹnikẹ́ni láàyè láti pọ́n wọn lójú;ó fi ọba bú nítorí tí wọn:

15. “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi,má sì ṣe wòlíì mi nibi.”

16. Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náàó sì pa gbogbo ìpèṣè oúnjẹ wọn run;

Sáàmù 105