24. Iṣẹ́ Rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá a Rẹ.
25. Bẹ́ẹ̀ ni òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìṣàlẹ̀ láìníyeohun alàyè tí tóbi àti kékeré.
26. Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,àti Léfíàtanì, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú Rẹ̀.
27. Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò Rẹ̀.
28. Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,wọn yóò kó o jọ;nígbà tí ìwọ bá là ọwọ Rẹ̀,a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.