Sáàmù 104:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní

3. Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi-àjà ìyẹ̀wù Rẹ.Ìwọ ti ó ṣe àwọ̀sánmọ̀ ni kẹ̀kẹ́-ogun Rẹìwọ tí ó ń rìn lórí àpá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

4. Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ Rẹ,Ọ̀wọ́ iná ni àwọn olùránsẹ́ Rẹ.

5. O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;tí a kò le è mi láéláé.

Sáàmù 104