Sáàmù 104:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Àwọn igi Olúwa ni a bomi rin dáradára,Kédárì tí Lébánónì tí ó gbìn.

17. Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọnbí ó se tí àkọ̀ ni, orí igi páìnì ni ilé Rẹ̀.

18. Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;àti àwọn àlàpà jẹ ààbò fún àwọn ehoro.

19. Òsúpá jẹ àmì fún àkókòòòrùn sì mọ̀ ìgbà tí yóò wọ̀.

20. Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,nínú èyí tí gbogbo ẹ̀ranko igbó ń rìn kiri.

Sáàmù 104