Sáàmù 103:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Olúwa ti pèsè ìtẹ́ Rẹ̀ nínú ọ̀run,ìjọba Rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20. Yin Olúwa, ẹ̀yin ańgẹ́lì Rẹ̀ tí ó ní ipá,tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mọ́

21. Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run Rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.

22. Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ níibi gbogbo ìjọba Rẹ̀.Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Sáàmù 103