Sáàmù 101:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:iṣẹ́ àwọn tí o yapa ni èmi kórìírawọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.

4. Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ miÈmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

5. Ẹnikẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnikejì Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,oun ní èmi yóò gé kúròẹni tí ó bá gbé ojú Rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,òun ní èmi kì yóò faradà fún.

6. Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtọ́ lórí ilẹ̀,kí wọn kí ó le máa bá mi gbé;ẹni tí o bá ń rìn ọ̀nà pípéòun ni yóò máa sìn mí.

7. Ẹni tí o bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,kò sí ẹni tí ń ṣèké ti yóò dúró ní iwájú mi.

8. Ní ojojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa lẹ́nu mọgbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;èmi yóò gé àwọn olùṣe búburúkúrò ní ìlú Olúwa.

Sáàmù 101