Sáàmù 100:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé

2. Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:Ẹ wá ṣíwájú Rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn

3. Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,kí ẹyin kí ó mọ̀ pétirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn Rẹ̀àti àgùntàn pápá Rẹ̀.

4. Ẹ lọ sí ẹnu ọ̀nà Rẹ̀ pẹlú ọpẹ́àti sí àgbàlá Rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ Rẹ̀.

Sáàmù 100