17. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Fáráò pé, Nítorí èyí ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, kí a sì le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.
18. Nítorí náà ni ó ṣe sàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú lí ọkàn le.
19. Ìwọ ó sì wí fún mi pé, kínni ó ha tún bá ni wí fún? Nítorí tani ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?
20. Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? Ohun tí a mọ, a máa wí fún ẹni tí ó mọ ọn pé, Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyì?
21. Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí àmọ̀, níní ìṣu kan náà láti ṣe apákan ní ohun èlò sí ọlá, àti apákan ní ohun èlò sí àìlọ́lá?