Róòmù 8:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò já mọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn.

19. Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run.

20. Nítórí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í se bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí.

21. Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkáararẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdibàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

22. Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí.

23. Kì í se àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkara wa pẹ̀lú, tí ó nbí àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkara wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìṣọdọmọ àní ìdáńdè ara wa.

24. Nítorí ìrètí tí a fi gbà wá là: ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í se ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí?

25. Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

26. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkáara rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa.

27. Ẹni tí ó sì ń wá ọkàn wò, ó mọ ohun ti inú ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.

28. Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń siṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.

29. Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, u kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn arákùnrin púpọ̀

30. Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kírísítì kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

31. Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?

Róòmù 8