Róòmù 8:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kírísítì ń gbé inú yín ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ẹran ara yín yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo.

11. Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jésù kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, òun yóò mú kí ara yín tí ó kú tún wà láàyè nípa sẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ kan náà tí ń gbé inú yín.

12. Nítorí náà ará, kò jẹ́ ọ̀rọ̀ iyàn fún un yín láti se nǹkan tí ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ ń rọ̀ yín láti se.

13. Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì sègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípaṣẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀yin sẹ́gun ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀ nínú yín, ẹ̀yin yóò yè.

14. Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run.

Róòmù 8