Róòmù 6:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Gbogbo èrò burúkú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́sẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

7. Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́

8. Níwọ̀n ìgbà tí ògbólógbòó ara yín tó ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ ti kú pẹ̀lú Kírísítì, àwa mọ̀ pé, ẹ̀yin yóò pín nínú ìyè titun rẹ̀.

9. Kírísítì ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́.

10. Kírísítì kú lẹ́ẹ̀kan soso, láti sẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láàyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

11. Nítorí náà, ẹ máa wo ògbólógbòó ara ẹ̀ṣẹ̀ yín gẹ́gẹ́ bí òkú tí kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Dípò èyí, máa gbé ìgbé ayé yín fún Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in fún un, nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa.

12. Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀sẹ̀ jọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kùfẹ̀ẹ̀ rẹ̀.

13. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ìkà, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ǹda wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára.

14. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.

Róòmù 6