Róòmù 3:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Kí a má rí i: bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé?

7. Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́sẹ̀?

8. Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bí wọn tọ́.

9. Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn wọn bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fi hàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

Róòmù 3