10. ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú:
11. Nítorí Olúwa kìí ṣe ojú ìsáájú ènìyàn.
12. Gbogbo àwọn tí ó sẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dálẹ́jọ́;
13. Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni aláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dáláre.
14. Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà àdánidá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin.
15. Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsìnyí.