Róòmù 10:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Títí ìsinsin yìí, wọn kò ì tíì mọ̀ pé, Kírísítì kú láti pèsè ohun gbogbo tí wọ́n ń fi àníyàn wá kiri nípa òfin fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, ó ti fi òpin sí gbogbo rẹ̀.

5. Nítorí pé Mósè kọ ọ́ pé, “Kí ènìyàn tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàlà (nípa òfin) gbà, ó ní láti ja àjàṣẹ́gun nínú gbogbo ìdánwò, kí ó sì wà láì dá ẹ̀ṣẹ̀ kan soso nínú gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.”

6. Ṣùgbọ́n ìgbàlà tí ó wà nípa ìgbàgbọ́ wí pé, “A kò níláti lọ wá inú ọ̀run láti mú Kírísítì wá sí ayé kí ó bá à lè ràn wá lọ́wọ́.”

7. Bẹ́ẹ̀ ni, a kò níláti wọ ìsà òkú lọ láti jí Kírísítì dìde.

8. Nítorí pé, ìgbàlà tí ènìyàn ń ní nípa ìgbẹ́kẹ̀lé, nínú Kírísítì, ìgbàlà tí àwa ń wàásù rẹ̀, wà ní àrọ́wọ́tó ẹnikọ̀ọ̀kan wa. Kódà, ó kínlẹ̀ sí wa tó bí ọkàn àti ẹnu wa ti kínlẹ̀ sí wa.

9. Nítorí pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Olúwa ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì jẹ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn pé Jésù Kírísítì ní Olúwa rẹ, a ó gbà ọ́ là.

10. Nítorí pé, nípa ìgbàgbọ́ nínú ọkàn ni ènìyàn le gbà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ni a sì fi ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn ní ti ìgbàgbọ́ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a sì sọ ìgbàlà wa di ohun tí ó dájú.

11. Nítorí pé, ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Kírísítì gbọ́ kò ní kábámọ̀; ojú kò ní ti olúwa rẹ̀ láéláé.”

12. Òtítọ́ ni èyí pé, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́, ìbáà ṣe Júù tàbí aláìkọlà; Ọlọ́run kan ni ó wà fún gbogbo wa, ó sì ń pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìwọ̀n fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè rẹ̀.

13. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sà à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”

Róòmù 10