Òwe 8:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.

20. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,ní ojú ọ̀nà òtítọ́,

21. mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mimo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

22. “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;

23. A ti yàn mí láti ayérayé,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.

Òwe 8